Àwọn ìpalára àti ìṣòro òògùn ìṣẹ́yún

Báwo ni ẹ̀jẹ̀ àti ìnira inú fífúnpọ̀ ṣe máa ń pọ̀ sí lẹ́yìn tí èèyàn bá lo misoprostol?

Fún àwọn kan, ìnira a máa pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ (fún ẹni tí inú rẹ̀ bá máa ń fúnpọ̀ nígbà nǹkan oṣù), ẹ̀jẹ̀ tí ó máa ń yọ náà sì máa ń pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ. Ẹ̀jẹ̀ dídì tí ó tóbi tó ọsàn náà lè jáde lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí o bá lo misoprostol. Fún àwọn obìnrin kan, ìrora inú fífúnpọ̀ yìí kò ní ga jara lọ, ẹ̀jẹ̀ náà ò sì ní ju ti nǹkan oṣù lọ.

Tí ẹ̀jẹ̀ ò bá jáde lẹ́yìn tí mo bá lo misoprostol ńkọ́?

Kàn sí elétò ààbò tí ẹ̀jẹ̀ ò bá jáde rárá tàbí kò pọ́, tí ìrora púpọ̀ (pàápàá ní èjìká ọ̀tún) tí apá ibuprofen ò ká bá tẹ̀lé e. Eléyìí lè jẹ́ àpẹẹrẹ oyún tí kò sí nínú ilé ọmọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wọ́pọ̀, ó léwu gan-an. O lè kàn sí àwọn ọ̀rẹ́ wa ní www.safe2choose.org láti bá akọ́ṣẹ́mọṣẹ olùgbaninímọ̀ràn nípa oyún ṣíṣẹ́ tí o bá rò pé oyún náà ò tíì wálẹ̀.

Tí ẹ̀jẹ̀ tí ó yọ lẹ́yìn tí mo bá lo òògùn ìṣẹ́yún bá ti oọ̀jù ńkọ́?

Béèrè fún ìtọ́jú tí ẹ̀jẹ̀ bá kún páàdì méjì fọ́nfọ́n láàrin wákàtí kan fún wákàtí méjì léraléra lẹ́yìn tí o lérò pé oyún náà ti wálẹ̀. Kíkún páàdì náà túmọ̀ sí pé ẹ̀jẹ̀ kún un láti iwájú dé ẹ̀yìn, ẹ̀gbẹ́ sí ẹ̀gbẹ́, àti wọnú.

Kí ni mo lè ṣe láti dín ìrora kù lẹ́yìn tí mo bá lo òògùn ìṣẹ́yún?

Lo ibuprofen mẹ́ta sí mẹ́rin (ọ̀kọ̀ọ̀kan 200mg) ní wákàtí mẹ́fà mẹ́fà tàbí mẹ́jọ mẹ́jọ sí ara wọn láti dín ìnira kù. O sì lè lo ibuprofen kí o tó lo misoprostol.

Ìgbà wo ni kí n dúró dì kí n tó lóyún lẹ́yìn tí mo bá ṣẹ́yún?

lO è lóyún lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ tí o bá ṣẹ oyún. Tí o bá máa ní àjọṣepọ̀, o lè lo nǹkan ìdènà oyún kí o má ba à ní oyún àìròtẹ́lẹ̀.

Ṣe mo lè mu nǹkan olómi bí mo ṣe máa ń mu ú tẹ́lẹ̀?

Lẹ́yìn tí misoprostol bá túká, o lè mu nǹkan olómi tí ó bá wù ọ́ (yàtọ̀ sí ọtí).

Ṣe mo lè mú ọtí nígbà tí àti lẹ́yìn tí mo bá lo òògùn ìṣẹ́yún?

Yẹra fún orí mímú ní àkókò yìí kí òògùn náà ba à lè ṣiṣẹ́ bí ó ṣe yẹ. Ọtí mímú lè mú kí ẹ̀jẹ̀ máa dà síi, ó sì tún lè ṣe ìdíwọ fún iṣẹ́ àwọn òògùn tí ó máa ń dín ìrora kù àti àwọn tí ó ń dènà àkóràn (fún àwọn tí ó ní ìṣòro kan tàbí ìkejì). Ní àkótán, a gbà ọ ní ìyànjú kí o yẹra fún ọtí títí yóò fi dá ọ lójú pé oyún náà ti wálẹ̀ tí o sì wà ní àlàáfíà.

Ìgbà wo ni àwọn ìpalára oyún ṣíṣẹ́ yóò tó lọ?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni oyún máa ń wálẹ̀ láàrín wákàtí mẹ́rin sí márùn-ún tí ara yóò sì bọ́ sípò láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún. Kò sì sí aburú nínú kí ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ máa yọ tàbí kán títí o ó fi rí nǹkan oṣù rẹ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí mẹ́rin.

Ṣé ó lè máa rẹ èèyàn tàbí kí inú rẹ̀ máa ru lẹ́yìn tí ó bá lo misoprostol?

Ó lè rẹ èèyàn tàbí kí ó ní inú rírú, òtútù àti arábìnrin gbígbóná ní àkókò yìí. Ọpọlọpọ obìnrin ni ó sì sọ pé bí àwọn ṣe mọ̀ pé oyún náà ti wálẹ̀ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dá, ara wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní balẹ̀.

Kí ni kí n ṣe tí oyún náà ò bá wálẹ̀ lẹ́yìn tí mo bá wálẹ̀ lẹ́yìn tí mo lo òògùn ìṣẹ́yún?

Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ iṣẹ́ abẹ ni wọ́n yóò fi gbé oyún lára obìnrin míì tí ó bá lo òògùn ìṣẹ́yún tí kò bá ṣiṣẹ́. Má ṣe gbàgbé pé ìtọ́jú wà fún irú oyún tí kò bá wálẹ̀ bẹ́ẹ̀ káàkiri àgbáyé. Ìwọ náà ní ẹ̀tọ́ sí ìtọ́jú yìí, kódà kí òfin má fi ààyè gba oyún ṣíṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè rẹ.

Báwo ni ẹ̀jẹ̀ àti ìnira inú fífúnpọ̀ ṣe máa ń pọ̀ sí lẹ́yìn tí èèyàn bá lo misoprostol?

Fún àwọn kan, ìnira a máa pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ (fún ẹni tí inú rẹ̀ bá máa ń fúnpọ̀ nígbà nǹkan oṣù), ẹ̀jẹ̀ tí ó máa ń yọ náà sì máa ń pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ. Ẹ̀jẹ̀ dídì tí ó tóbi tó ọsàn náà lè jáde lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí o bá lo misoprostol. Fún àwọn obìnrin kan, ìrora inú fífúnpọ̀ yìí kò ní ga jara lọ, ẹ̀jẹ̀ náà ò sì ní ju ti nǹkan oṣù lọ.

Tí ẹ̀jẹ̀ ò bá jáde lẹ́yìn tí mo bá lo misoprostol ńkọ́?

Kàn sí elétò ààbò tí ẹ̀jẹ̀ ò bá jáde rárá tàbí kò pọ́, tí ìrora púpọ̀ (pàápàá ní èjìká ọ̀tún) tí apá ibuprofen ò ká bá tẹ̀lé e. Eléyìí lè jẹ́ àpẹẹrẹ oyún tí kò sí nínú ilé ọmọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wọ́pọ̀, ó léwu gan-an. O lè kàn sí àwọn ọ̀rẹ́ wa ní www.safe2choose.org láti bá akọ́ṣẹ́mọṣẹ olùgbaninímọ̀ràn nípa oyún ṣíṣẹ́ tí o bá rò pé oyún náà ò tíì wálẹ̀.

Tí ẹ̀jẹ̀ tí ó yọ lẹ́yìn tí mo bá lo òògùn ìṣẹ́yún bá ti oọ̀jù ńkọ́?

Béèrè fún ìtọ́jú tí ẹ̀jẹ̀ bá kún páàdì méjì fọ́nfọ́n láàrin wákàtí kan fún wákàtí méjì léraléra lẹ́yìn tí o lérò pé oyún náà ti wálẹ̀. Kíkún páàdì náà túmọ̀ sí pé ẹ̀jẹ̀ kún un láti iwájú dé ẹ̀yìn, ẹ̀gbẹ́ sí ẹ̀gbẹ́, àti wọnú.

Kí ni mo lè ṣe láti dín ìrora kù lẹ́yìn tí mo bá lo òògùn ìṣẹ́yún?

Lo ibuprofen mẹ́ta sí mẹ́rin (ọ̀kọ̀ọ̀kan 200mg) ní wákàtí mẹ́fà mẹ́fà tàbí mẹ́jọ mẹ́jọ sí ara wọn láti dín ìnira kù. O sì lè lo ibuprofen kí o tó lo misoprostol.

Ṣé mo lè jẹun bí mo ṣe máa ń jẹ ẹ́ lẹ́yìn tí mo bá lo òògùn ìṣẹ́yún tán?

Lẹ́yìn tí misoprostol bá túká tán, o lè jẹun bí ó ṣe wù ọ́. Àwọn oúnjẹ tí kò oómi (bíi bisikíítì gbígbẹ àti tósìtì) máa ń dín inú rírun kù. Ẹ̀fọ́, ẹyin, ẹran (àwọn ẹran tí ó máa ń pupa tí a bá ṣe é tán) máa ń dá àwọn ohun tí ó ti bá ẹ̀jẹ̀ lọ padà sínú ara.

Ṣe mo lè mu nǹkan olómi bí mo ṣe máa ń mu ú tẹ́lẹ̀?

Lẹ́yìn tí misoprostol bá túká, o lè mu nǹkan olómi tí ó bá wù ọ́ (yàtọ̀ sí ọtí).

Ṣe mo lè mú ọtí nígbà tí àti lẹ́yìn tí mo bá lo òògùn ìṣẹ́yún?

Yẹra fún orí mímú ní àkókò yìí kí òògùn náà ba à lè ṣiṣẹ́ bí ó ṣe yẹ. Ọtí mímú lè mú kí ẹ̀jẹ̀ máa dà síi, ó sì tún lè ṣe ìdíwọ fún iṣẹ́ àwọn òògùn tí ó máa ń dín ìrora kù àti àwọn tí ó ń dènà àkóràn (fún àwọn tí ó ní ìṣòro kan tàbí ìkejì). Ní àkótán, a gbà ọ ní ìyànjú kí o yẹra fún ọtí títí yóò fi dá ọ lójú pé oyún náà ti wálẹ̀ tí o sì wà ní àlàáfíà.

Ìgbà wo ni àwọn ìpalára oyún ṣíṣẹ́ yóò tó lọ?

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni oyún máa ń wálẹ̀ láàrín wákàtí mẹ́rin sí márùn-ún tí ara yóò sì bọ́ sípò láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún. Kò sì sí aburú nínú kí ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ máa yọ tàbí kán títí o ó fi rí nǹkan oṣù rẹ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sí mẹ́rin.

Ṣé ó lè máa rẹ èèyàn tàbí kí inú rẹ̀ máa ru lẹ́yìn tí ó bá lo misoprostol?

Ó lè rẹ èèyàn tàbí kí ó ní inú rírú, òtútù àti arábìnrin gbígbóná ní àkókò yìí. Ọpọlọpọ obìnrin ni ó sì sọ pé bí àwọn ṣe mọ̀ pé oyún náà ti wálẹ̀ ni pé ẹ̀jẹ̀ ń dá, ara wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní balẹ̀.

Kí ni kí n ṣe tí oyún náà ò bá wálẹ̀ lẹ́yìn tí mo bá wálẹ̀ lẹ́yìn tí mo lo òògùn ìṣẹ́yún?

Ó ṣeéṣe kí ó jẹ́ iṣẹ́ abẹ ni wọ́n yóò fi gbé oyún lára obìnrin míì tí ó bá lo òògùn ìṣẹ́yún tí kò bá ṣiṣẹ́. Má ṣe gbàgbé pé ìtọ́jú wà fún irú oyún tí kò bá wálẹ̀ bẹ́ẹ̀ káàkiri àgbáyé. Ìwọ náà ní ẹ̀tọ́ sí ìtọ́jú yìí, kódà kí òfin má fi ààyè gba oyún ṣíṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè rẹ.

Itọkasi

Oju opo wẹẹbu yii le nilo awọn kuki alailorukọ ati ọpọlọpọ awọn iṣẹ ẹnikẹta lati ṣiṣẹ daradara. O le ka Awọn ofin & Awọn ipo wa ati Awọn ilana Ìpamọ . Nipa tẹsiwaju lati lo aaye yii o fun wa ni igbanilaaye rẹ lati ṣe eyi.