Ṣíṣẹ́ oyún tí ó ti pé ọ̀sẹ̀ 10 sí 13 ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó.

Ó sì lè ṣẹ́ oyún ọ̀sẹ̀ 10 sí 13 pẹ̀lú òògùn ìṣẹ́yún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó láìsí ewu, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wà tí a gbọ́dọ̀ ro.

Àìléwu oyún ṣíṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀sẹ̀.

Tí o bá ṣẹ́yún ní àìpẹ́ tí o níi, kò sí ewu púpọ̀. Bí oyún náà ṣe ń dàgbà síi ni ewu náà ń pọ̀ síi, àwòrán tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí sàfihàn èyí. Lóòótọ́, bí oyún ṣe ń dàgbà ni ewu ń pọ̀ síi, ṣùgbọ́n oyún ọ̀sẹ̀ 13 sì ṣé é ṣẹ́ láìsí ewu ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó.

Àwọn nǹkan wo ni ó máa rí tí ó bá ṣẹ́ oyún tí ó ti ju ọ̀sẹ̀ 10 lọ?

Oyún ṣíṣẹ́ ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ yọ lára àwọn obìnrin. Ẹ̀jẹ̀ yìí lè pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ, ẹ̀jẹ̀ dídì sì lè wà níbẹ̀. Ó ṣeéṣe kí àwọn tí oyún wọn bá wà láàrin ọ̀sẹ̀ 10 sí 13 rí ohun tí wọn ò dá mọ̀, tàbí tí ó jọ awọ kékeré. Eléyìí ò kí ń ṣe nǹkan èèmọ̀, má ṣe jáyà. Ara àwọn àmì pé oyún náà ti ń wálẹ̀ bí ó ṣe yẹ ní. O lè da ẹ̀jẹ̀ dídì tàbí awọ náà sí inú ilé ìgbọ̀nsẹ̀, bíi nǹkan oṣù. Tí òfin bá lòdì sí oyún ṣíṣẹ́ ní agbègbè rẹ, sọra tí o bá fẹ́ sọ àwọn ohun tí àwọn ènìyàn lè dámọ̀ nù. Má sì ṣe sọ ọ́ sí ibi tí àwọn ènìyàn yóò ti ríi.

Àwọn òǹkọ̀wé:

  • Gbogbo àkóónú tí a fihàn lórí ayélujára yìí ni a kọ nípa ẹgbẹ́ HowToUseAbortionPill.org ní ìbámu pẹ̀lu àwọn òṣùwọ̀n àti ìlànà láti Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ [The National Abortion Federation], Ipas, Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé [the World Health Organization], DKT L’ágbàyé àti carafem.
  • Àjọ Àpapọ̀ Oyún ṣíṣẹ́ (NAF) jẹ́ ẹgbẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àwọn olùpèsè oyún ṣíṣẹ́ ní Àríwá Amẹ́ríkà, àti aṣíwájú ní ìgbìyànjú fún yíyàn láti yọ oyún. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2020 Àwọn ìtọ́ni Òfin Ìṣègùn tí NAF gbéjáde.
  • Ipas jẹ́ ẹgbẹ́ kansoso ní àgbàyé tí ó ńtẹjúmọ́ mímú kí rírí ààyè sí oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu àti àbójútó dídènà oyún níní fẹ̀ si. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu Ìmúdójú-ìwọ̀n Ìléra Bíbímọ 2019 tí Ipas gbéjáde.
  • Àjọ tí ó ńbójútó Ìlera L’ágbàyé (WHO) jẹ́ àjọ tí ó mọ nǹkan lámọ̀já ti ẹ̀ka Àjọ Àpapọ̀ orílẹ̀-èdè L’ágbàyé tí ó ní ojúṣe fún ìlera àwùjọ l’ágbàyé. Àkóónú lórí HowToUseAbortionPill.org wà ní ìbámu pẹ̀lu 2012 Oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu: ìtọ́ni iṣẹ́ ọnà àti òfin fún ètò ìlera tí WHO gbéjáde.
  • DKT L’ágbàyé jẹ́ àjọ tí a ti forúkọ rẹ̀ sílẹ̀, tí kò sí fún èrè tí a dá sílẹ̀ ní ọdún 1989 láti tẹjúmọ́ agbára ìlànà mímú àwùjọ yípadà fún àǹfààní àwùjọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣe àìní tí ó gá jù lọ fún fífi ètò sí ọmọ bíbí, dídènà HIV/AIDS àti oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu.
  • carafem jẹ́ alátagbà ìṣègùn tí ó ńpèsè oyún ṣíṣẹ́ láìsí ewu èyìtí ó rọrùn àti fífi ètò sí ọmọ bíbí nípasẹ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kí àwọn ènìyàn lè ṣe àkóso iye àwọn ọmọ àti àlàfo tí ó wà láàrín wọn.

Itọkasi:

Oju opo wẹẹbu yii le nilo awọn kuki alailorukọ ati ọpọlọpọ awọn iṣẹ ẹnikẹta lati ṣiṣẹ daradara. O le ka Awọn ofin & Awọn ipo wa ati Awọn ilana Ìpamọ . Nipa tẹsiwaju lati lo aaye yii o fun wa ni igbanilaaye rẹ lati ṣe eyi.