Ki o tó lo òògùn náà

Rii daju pe o lero ni kikun alaye ati imurasilẹ ṣaaju nini iṣẹyun pẹlu egbogi awọn.

Ẹ̀rọ ìṣirò oyún

Ó tó ọ̀sẹ̀ mélòó tí ó lóyún? Ìwádìí tí fihàn pé oyún tí kò bá tíì tó ọ̀sẹ̀ 13 lẹ́yìn nǹkan oṣù ìkẹ́yìn ni wọn sáábà máa ń fara mọ́ kí èèyàn ṣé. Fi ẹ̀rọ ìṣirò oyún ṣírò iye ọ̀sẹ̀ tí oyún rẹ ti pé lẹ́yìn tí ó ṣe nǹkan oṣù kẹ́yìn.

Tí nǹkan oṣù rẹ bá bẹ̀rẹ̀ ní tàbí lẹ́yìn:

Ó sì lè lo òògùn ìṣẹ́yún.

Àwọn èrò

Ti o ba ni IUD

Tí ẹ̀rọ ìdènà oyún (òníkíká tàbí èyí tí ó ní "progesterone" nínú) bá wà nínú ilé ọmọ, o gbọ́dọ̀ yọọ́. Dandan ni kí o yọ ẹ̀rọ ìdènà oyún kí o tó lo òògùn ìṣẹ́yún.

Ti o ba gbe pẹlu HIV

Tí ó bá ní kòkòrò àrùn kògbóògùn HIV lára, ríi dájú pé àárẹ̀ ò mú ọ, o ń lo òògùn rẹ déédé, ara rẹ sì yá.

Ti O ba jẹ Ifiyesi pẹlu asiri

ti o ba ni aniyan nipa titọju iṣẹyun rẹ bi ikọkọ bi o ti ṣee ṣe, tọju egbogi iṣẹyun labẹ ahọn dipo obo. Tí ó bá fẹ́ ní àwọn ìṣòro kan, èyí kò súnmọ́ kí ó ṣẹlẹ, tí o sì nílò ìtọ́jú elétò ààbò, ó ṣeéṣe kí wọ́n rí òògùn náà ní ojú ara rẹ. Èyí lè mú kí wọ́n fi ẹjọ́ rẹ sún ní ìlú tí òfin ò fààyè gba oyún ṣíṣẹ́.

Ti o ba n mu ọmu mu

Tí o bá ń fọ́mọ lọ́yàn lọ́wọ́ tí o fi lo misoprostol, ọmọ náà lè ní ìgbẹ́ gbuuru. Láti dènà èyí, dúró fún bíi wákàtí mẹ́rin lẹ́yìn tí o bá lo òògùn yìí tán kí o tó tún fún ọmọ lọ́yàn.

Ti o ba ni Hemoglobin kekere

Tí o bá ní àrùn anémíà (tí áyọ́ọ̀nù ò bá tó nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ), wá elétò ààbò tí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ò ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ nítorí bí ó bá nílò ìrànlọ́wọ́. Tí anémíà rẹ bá lè, bá dókítà sọ̀rọ̀ kí o lo òògùn ìṣẹ́yún.

Ìmọ̀ràn

Rọra jẹun (o lè jẹ bisikíítì pẹlẹbẹ tí ò ní ṣúgà tàbí tósíìtì láti dín ebi kù).

Yóò dára bí ẹnìkan bá le dúró tì ọ láti ṣe ìtọ́jú rẹ.

Mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ní àkókò tí o bá ń ṣẹ́yún.

O lè lo òògùn "ibuprofen" kí o tó lo misoprostol láti dín ìnira inú fífúnpọ̀ kù.

Wà ní ibi tí ó pamọ́ tí o sì ti lè fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ fún wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn tí o bá lo òògùn tán kí o tó lo misoprostol.

Ṣe ètò ààbò kí o tó lo òògùn ìṣẹ́yún nítorí tí o bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì.

Ṣíṣe ètò ààbò

Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwọn oníṣègùn tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí àti àwọn tí ó ní ṣe pẹ̀lú àwọn àrùn tí ó ń gbógun ti àwọn ẹ̀yà ara obìnrin tí ó ní ṣe pẹ̀lú ọmọ bíbí ti ìlú Amẹ́ríkà, ṣíṣẹ́ oyún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó ní ìdá àkọ́kọ́ nínú mẹ́ta àkókò oyún jẹ́ ọ̀kan tí kò mú ewu lọ́wọ́. O lè lo àwọn ìbéèrè tí a fi sí ìsàlẹ̀ yìí láti ṣe ètò ààbò rẹ torí a ò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀.

Níbo ni ilé ìwòsàn pàjáwìrì tí ó máa ń ṣí yíká aago tí ó súnmọ́ jù wà?

Ó gbọ́dọ̀ lè débẹ̀ láàrin wákàtí kan (tí o bá ní anémíà, o gbọ́dọ̀ lè débẹ̀ láàrin ọgbọ̀n ìṣẹ́jú)

Báwo ni o ṣe máa dé ilé ìwòsàn pàjáwìrì náà?

Ṣe ẹni tí ó lè wà ọ́ yóò wà? Ṣé takisí lo fẹ́ wọ̀ ni àbí ọkọ èrò? Èló ni owó ọkọ̀ àti pé ṣé ó máa ń ṣiṣẹ́ yíká aago? Má ṣe gbàgbé pé ó léwu láti wa ara rẹ lọ sí ilé ìwòsàn ní irú àsìkò yìí.

Kí ni o máa sọ fún àwọn dókítà rẹ?
  • Ṣe òfin fi ààyè gba oyún ṣíṣẹ́ ni ìlànà ìṣègùn òyìnbó tàbí ní ilé ní ibi tí ò ń gbé? Kí ni o lè sọ fún wọn tí wọn yóò fi mọ̀ pé o nílò ìtọ́jú tí kò ní kóbá ọ? Tí o bá ń wá ohun tí o lè sọ, wo àwọn àbá tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí
  • Ní àwọn orílẹ̀ èdè kan, oyún ṣíṣe ní ìlànà ìṣègùn oyinbo tàbí ní ilé lòdì sí òfin. Èyí túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ mọ ohun tí o máa sọ fún àwọn dókítà bí o bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì tí kò ní ṣàkóbá fún ọ. Àwọn àmì oyún ṣíṣe ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó ò yàtọ̀ sí ìgbà tí oyún bá wálẹ̀ fúnraarẹ̀. O lè sọ àwọn nǹkan bíi

Itọkasi:

Oju opo wẹẹbu yii le nilo awọn kuki alailorukọ ati ọpọlọpọ awọn iṣẹ ẹnikẹta lati ṣiṣẹ daradara. O le ka Awọn ofin & Awọn ipo wa ati Awọn ilana Ìpamọ . Nipa tẹsiwaju lati lo aaye yii o fun wa ni igbanilaaye rẹ lati ṣe eyi.