Ọ̀nà méjì ni o lè gbà ṣẹ́yún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó. Méjèèjì ni ó sì máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa:
Ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ lè yọ lára àwọn kan nígbà tí wọ́n bá lo mifepristone tí àwọn míràn ò sì ní rí ẹ̀jẹ̀ rárá. Kò sí èyí tí ó béwu dé nínú méjèèjì.
Inú fífúnpọ̀ àti ẹ̀jẹ̀ yíyọ ni ó wọ́pọ̀ jù. Àwọn àmì yìí sì wúlò nítorí pé wọ́n ń fihàn pé òògùn náà ń ṣiṣẹ́. Ṣùgbọ́n báwo ni ìrora inú fífúnpọ̀ àti ẹ̀jẹ̀ tí yóò yọ ṣe máa pọ̀ tó?
Fún àwọn kan, ìrora inú fífúnpọ̀ yìí máa ń pọ̀ gàn - ó máa ń le ju ti ìgbà nǹkan oṣù lọ (fún ẹni tí ó bá máa ń ní)
Fún àwọn kan, ẹ̀jẹ̀ náà máa ń pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ. Ó wọ́pọ̀ kí ẹ̀jẹ̀ dídì yọ lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí wọn bá lo misoprostol. Iye ọ̀sẹ̀ tí oṣù náà jẹ́ ni yóò sọ bí ẹ̀jẹ̀ dídì náà yóò ṣe tóbi tó.
Fún àwọn obìnrin mìíràn, ìrora inú fífúnpọ̀ náà kò ní kọjá àfaradà, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ náà ò ní pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ.
Má ṣe jáyà tí ẹ̀jẹ̀ àti ìrora inú fífúnpọ̀ bá pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ.
Tí ìrora inú fífúnpọ̀ náà bá pọ̀ jù, ó lè lo ibuprofen. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè, o lè ra ibuprofen (200mg) láìjẹ́ pé dókítà kọ ọ́ fún ọ. Lo mẹ́ta mẹ́ta sí mẹ́rin mẹ́rin (ọ̀kọ̀ọ̀kan, 200mg)lẹ́yìn wákàtí mẹ́fà sí mẹ́jọ sí ara wọn.
Ó lè jẹ, kí o sì mu bí ó ṣe wù ọ́.
Wà ní ibi tí ó fọkànbalẹ títí ara rẹ yóò fi balẹ̀.
Ara ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin máa ń bọ́ sí ipò láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún.
Àkíyèsí:
Tí o bá ṣe àyẹ̀wò lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí o ṣẹ́yún, àyẹ̀wò yóò sì fi hàn pé o lóyún nítorí àwọn hòmóònù tí ó ṣì wà lára rẹ. Tí àwọn àmì pé o lóyún (àárẹ̀ ara, ọyàn rírọ̀, inú rírú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) bá sì ń yọ ọ́ lẹ́nu lẹ́yìn tí o lo òògùn ìṣẹ́yún, lọ rí dókítà.
Tí oyún bá ń wálẹ̀, àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí kò mú ewu lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n má ṣe sàsùn para. Nǹkan lè ti fẹ́ yíwọ́ tí ó ba rí àwọn àpẹẹrẹ ìsàlẹ̀ wọ̀nyí:
Tí ẹ̀jẹ̀ bá kún páàdì méjì láàrin wákàtí kan lẹ́yìn tí o lérò pé oyún náà ti wálẹ̀, o ní láti rí elétò ìlera ní kíákíá nítorí ẹ̀jẹ̀ náà ti pọ̀jù. Kí ẹ̀jẹ̀ kún páàdì túmọ̀ sí pé páàdì náà kún fún ẹ̀jẹ̀ láti iwájú dé ẹ̀yìn, ẹ̀gbẹ́ sí ẹ̀gbẹ́, àti dénú.
Tí ìrora náà bá pọ̀ tí òògùn ibuprofen ò sì kápá rẹ, béèrè fún ìtọ́jú. Irú ìrora báyìí lè wáyé tí nǹkan bá ṣe oyún náà. A gbà aláboyún tí ó bá ń jẹ ìrora tí apá ibuprofen ò ká láti rí elétò ìlera nítorí ó léwu.
Ara rẹ lè máa gbóná, kí inú rẹ máa ru tàbí kí o máa bì ní ọjọ́ tí o bá lo misoprostol. Lẹ́yìn èyí, ó yẹ kí ara r̀ máa yá síi ni. Ṣùgbọ́n tí ó bá ń rẹ ọ síi, yára lọ rí dókítà.
Oju opo wẹẹbu yii le nilo awọn kuki alailorukọ ati ọpọlọpọ awọn iṣẹ ẹnikẹta lati ṣiṣẹ daradara. O le ka Awọn ofin & Awọn ipo wa ati Awọn ilana Ìpamọ . Nipa tẹsiwaju lati lo aaye yii o fun wa ni igbanilaaye rẹ lati ṣe eyi.