Ó sì lè ṣẹ́ oyún ọ̀sẹ̀ 10 sí 13 pẹ̀lú òògùn ìṣẹ́yún ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó láìsí ewu, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wà tí a gbọ́dọ̀ ro.
Tí o bá ṣẹ́yún ní àìpẹ́ tí o níi, kò sí ewu púpọ̀. Bí oyún náà ṣe ń dàgbà síi ni ewu náà ń pọ̀ síi, àwòrán tí ó wà ní ìsàlẹ̀ yìí sàfihàn èyí. Lóòótọ́, bí oyún ṣe ń dàgbà ni ewu ń pọ̀ síi, ṣùgbọ́n oyún ọ̀sẹ̀ 13 sì ṣé é ṣẹ́ láìsí ewu ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó.
Oyún ṣíṣẹ́ ní ìlànà ìṣègùn òyìnbó máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ yọ lára àwọn obìnrin. Ẹ̀jẹ̀ yìí lè pọ̀ ju ti nǹkan oṣù lọ, ẹ̀jẹ̀ dídì sì lè wà níbẹ̀. Ó ṣeéṣe kí àwọn tí oyún wọn bá wà láàrin ọ̀sẹ̀ 10 sí 13 rí ohun tí wọn ò dá mọ̀, tàbí tí ó jọ awọ kékeré. Eléyìí ò kí ń ṣe nǹkan èèmọ̀, má ṣe jáyà. Ara àwọn àmì pé oyún náà ti ń wálẹ̀ bí ó ṣe yẹ ní. O lè da ẹ̀jẹ̀ dídì tàbí awọ náà sí inú ilé ìgbọ̀nsẹ̀, bíi nǹkan oṣù. Tí òfin bá lòdì sí oyún ṣíṣẹ́ ní agbègbè rẹ, sọra tí o bá fẹ́ sọ àwọn ohun tí àwọn ènìyàn lè dámọ̀ nù. Má sì ṣe sọ ọ́ sí ibi tí àwọn ènìyàn yóò ti ríi.
Oju opo wẹẹbu yii le nilo awọn kuki alailorukọ ati ọpọlọpọ awọn iṣẹ ẹnikẹta lati ṣiṣẹ daradara. O le ka Awọn ofin & Awọn ipo wa ati Awọn ilana Ìpamọ . Nipa tẹsiwaju lati lo aaye yii o fun wa ni igbanilaaye rẹ lati ṣe eyi.